Ìwé Sáàmù 49:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé

2Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré talákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!

3Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ìsọ láti ọkàn mi yóò mú òye wá

4Èmi yóò yí etí mi sí òwe olókùn ni èmi yóò ṣi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mí sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

4

5Èéṣé ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú àti ayan nijẹ yí mi ká,

6Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọpọlọpọ ọrọ̀ wọn

7Kò sí ọkùnrin tí o le ra ẹ̀mí ẹnìkejì Rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run.

8Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan Rẹ̀

9Níti ki ó máa wà títí ayé láì rí ìsà òkú.

9

10Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú sègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn

11Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé ibùgbé wọn láti ìrandé ìran wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn

12Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ o sì dàbí ẹranko tí o sègbé

13Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí o gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí o gba ọ̀rọ̀ wọn.

13Sela

14Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ní yóò jọba lórí wọn ní òwúrọ̀; Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́ isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.

15Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara Rẹ̀.

15

16Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnikan bá di ọlọ́rọ̀ Nígbà tí ìyìn ilé Rẹ̀ ń pọ̀ síi

17nítorí kì yóò mú òun kan dání nígbà tí ó bá kú, ògo Rẹ̀ kòní báa sọ̀kálẹ̀ sí ipò òkú

18Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara Rẹ̀. Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere

19Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba Rẹ àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>