Ìwé Sáàmù 50:1-23 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, Ọlọ́run Alágbára sọ̀rọ̀ kí o sì pè ayé jọ láti ìlà oorùn títí dé ìwọ̀ Rẹ̀.

2Láti Síónì wá, pípé ni ẹwà, Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀

3Ọlọ́run ń bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́, iná yóò máa jó níwájú Rẹ̀, àti ní àyíká Rẹ̀ ni ẹ̀fúfù líle yóò ti máa jà ká.

4Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé, kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn Rẹ̀.

5“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi”.

6Àwọn ọ̀run sọ̀rọ̀ òdodo Rẹ̀, Nítorí òun fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́

7Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, èmi yóò jẹrìí sí ọ: èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run Rẹ.

8Èmi kí yóò bá ọ wí nítorí àwọn ìrúbọ Rẹ̀ tàbí ọrẹ̀ ẹbọ sísun Rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi ní ìgbà gbogbo.

9Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí ó kọ fún un tàbí kí o mú ewúré láti inú agbo ẹran Rẹ̀

10Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmí àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.

11Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyé tí ó wà ní orí ilẹ ni tèmi

12Bí ebi tílẹ̀ ń pá mí, èmi kì yóò sọ fún ọ, nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo tí ó wa ní inú Rẹ̀.

13Ǹjẹ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí mú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́?

14Rú ẹbọ ọrẹ sí Ọlọ́run san ẹ̀jẹ̀ Rẹ fún ọ̀gá ògo,

15Kí o sì pe mí ni ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.

15

16Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn ènìyàn búburú: “Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mu mi ní ẹnu Rẹ?

17Ìwọ kórìíra àsẹ mi ìwọ sì sá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan

18Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́-ọn ìwọ sì da ara Rẹ̀ dé àwọn alágbèrè

19Ìwọ lo ẹnu Rẹ̀ fún aburú ìwọ sì ń fi ahọ́n Rẹ pète ẹ̀tàn

20Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí ará-kun-rin Rẹ, ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá Rẹ jẹ́

21Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́; ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara Rẹ.

21

22“Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run Bí bẹ́ ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹ́pẹ̀rẹ́ láì sí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀

23Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà Rẹ̀ ṣe kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>