Ìwé Sáàmù 51:1-19 BYB2014 - Bible AI

1Sàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìdúró sinsin ìfẹ́ Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú Rẹ̀ kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.

2Wẹ gbogbo àìṣedédé mi nù kúrò kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

2

3Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.

4ⓐ Sí ọ, ìwọ nìkan soso, ni mo sẹ̀ sí ni mo sì ṣe búburú níwájú Rẹ̀, kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀ kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọbá ń ṣe ìdájọ́.

5Ní tòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.

6Ní tòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú; ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀ kọ̀.

6

7Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé ísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju sínóò lọ.

8Jẹ́ kí ń gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn; jẹ́ kí gbogbo egúngún tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.

9Pa ojú Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédé mi rẹ́.

9

10Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.

11Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú Rẹ̀ kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ mi.

12Mú ayọ̀ ìgbàlà Rẹ̀ tọ̀ mí wá kí o sì fún mí ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ àwọn Olùrékọjá ní ọ̀nà Rẹ̀, àwọn ẹlẹ́sẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

14Gbàmí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi, ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo Rẹ kíkan.

15OLÚWA, sí mi ní ètè mi gbogbo, àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn Rẹ̀.

16Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá; Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọọrẹ̀-ẹbọ sísun

17Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbínújẹ́ ọkan ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.

17

18Ṣe rere ní dídùn inú Rẹ sí Síónì ṣe rere; tún odi Jérúsálẹ́mù mọ.

19Nígbà náà ni inú Rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo, pẹ̀lú ọrẹ-ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun, nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rúbọ lórí pẹpẹ Rẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>