Ìwé Sáàmù 52:1-9 BYB2014 - Bible AI

1Èéṣé tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin? Oore Ọlọ́run dúró pẹ́ títí

2Ahọ́n Rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun; ó dà bí abẹ mímú, ìwọ ẹni tí ń hùwà ìrẹ́jẹ.

3Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ire lọ, àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.

4Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

4

5Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé, yóò sì dì ọ́ mú, yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó Rẹ yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.

5Sela

6Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù wọn yóò sì rẹ́rìn-ín Rẹ̀, wí pé,

7Èyi ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára Rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ Rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé ó sì mu ara Rẹ̀ le nínú ìwà búburú Rẹ̀.

7

8Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Ólífì tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run; Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé.

9Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe; èmí ní ìrètí nínú orúkọ Rẹ, nítorí orúkọ Rẹ dára. Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>