Ìwé Sáàmù 53:1-6 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ  ⓑ Asiwèrè wí ní ọkàn Rẹ̀ pé: “Ọlọ́run kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú; kò sì sí ẹnìkan tí ń ṣe rere.

2Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn láti wò bóyá ẹnìkan wà tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run.

3Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

3

4Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀? Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?

5Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá níbì tí ẹ̀rù kò gbé sí nítorí Ọlọ́rún tí fọ́n egungun àwọn tí ó dótì ọ́ ká; ìwọ tí dójú tì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.

5

6Ìgbàlà Ísírẹ́lì ìbá jáde wá láti Síónì! Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jákọ́bù yọ̀ kí inú Ísírẹ́lì sì máa dùn!

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>