Ìwé Sáàmù 54:1-7 BYB2014 - Bible AI

1Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ Rẹ: dá mi láre nípa agbára Rẹ.

2Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run; fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

3Àwọn àlejò ń dìde sí mí. Àwọn aláìláàánú ènìyàn ń wá ayé mi àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.

3

4Kíyèsí i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi; OLÚWA ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ.

4

5Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi; pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ.

5

6Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ èmi yóò yin orúkọ Rẹ, OLÚWA, nítorí tí ó dára.

7Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìborí lórí ọ̀ta mi.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>