Ìwé Sáàmù 55:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run, Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:

2Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn. Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo

3Sí ohùn àwọn ọ̀ta ni, nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú; nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

3

4Ọkàn mi wà nínú ìrọra pẹ̀lú; ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.

5Ìbẹ̀rù àti ìwàrírí wa sí ara mi; ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.

6Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

7Èmi ìbá sá lọ jìnnà réré kí ń sì dúró sí ihà;

8Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò, jìnnà kúrò nínú ìjì àti èfúùfù líle.”

8

9Da àwọn ẹni búburú láàmú, OLÚWA, da ahọ́n wọn rú, nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.

10Ọ̀sán àti oru ní wọ́n fí ń rìn gbogbo odi kiri; àrankàn àti èébú wà láàrin Rẹ̀.

11Ìwà búburú ń bẹ ní àárin Rẹ̀; ìdẹ́rùbà àti irọ́ kò kúrò ní ìgboro Rẹ̀.

11

12Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi, èmi yóò fara mọ́ ọn; tí ọ̀ta bá gbé ara Rẹ̀ ga sími, èmi ibá sá pamọ́ fún un.

13Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó sún mọ́ mi,

14pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádún adùn ìdàpọ̀ bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwujọ ní ilé Ọlọ́run.

14

15Kí ikú kí ó dé bá wọn, Kí wọn ó lọ láàyè sí isà òkú, Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà, nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

15

16Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; OLÚWA yóò sì gbà mí.

17Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sunkún jáde nínú ìpọ́njú, o sì gbọ́ ohùn mi.

18Ó rà mí padà láìléwu kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.

19Ọlọ́run yóò gbọ́ yóò sì pọ́n wọn lójú àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbà a nì— Nítorí tí wọn kò ní àyípadà, tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

19Sela

20Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ Rẹ̀; ó ti bá májẹ̀mú Rẹ̀ jẹ́.

21Ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ̀ kúnná ju òrí àmọ́, ṣùgbọ́n ogun ija wà ni àyà Rẹ̀; ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífà yọ ní wọn.

21

22ⓐ Gbé ẹrù Rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ OLÚWA yóò sì mú ọ dúró; òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

23Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi wá sí ihò ìparun; Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

23Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>