1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbọ́nára lépa mi; ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára.
2Àwọn ọ̀ta mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́ àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.
2
3Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bàmí, èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ Rẹ nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?
4
5Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́ wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
6Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba Wọn ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
6
7Wọ́n ha le mú un jẹ gbé? Ní ìbínú Rẹ, Ọlọ́run, wó àwọn ènìyàn yìí lulẹ̀ Ọlọ́run!
8Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omije mi sí ìgò Rẹ wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ Rẹ bí?
8
9Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́ nípa èyí ní mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi
10Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú OLÚWA, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀:
11Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi: ẹ̀rù kì yóò bà mí kí ni ènìyàn le ṣe sí mi?
11
12Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ Rẹ Ọlọ́run: èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
13Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú, kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.