Ìwé Sáàmù 57:1-11 BYB2014 - Bible AI

1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú Rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí síbi ìyẹ́ apá Rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

2Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run gíga jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́ fún mi.

3Òun yóò ránsẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mì mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi. Ọlọ́run yóò rán àánú Rẹ̀ àti òdodo Rẹ̀ jáde.

3

4Mo wà ní àárin àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú àwọn ènìyàn tí ẹ̀yin wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n Rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

4

5Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ kí ògo Rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

6Wọn ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi: a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi: ṣùgbọ́n wọn ti jìn ṣíbẹ̀ fún ara wọn.

6

7ⓐ Ọkàn mi tí múra Ọlọ́run; ọkàn mí ti múra, èmi ó kọrin èmi ó si máa kọrin ìyìn.

8Jí, ìwọ ọkàn mi! Jí, ohun orin èlò àti dùùrù! Èmi tìkárami, yóò si jí ní kùtùkùtù.

8

9Èmi ó máa yín ọ, OLÚWA, láàrin àwọn orílẹ̀ èdè; èmi ó máa kọrin sí ọ láàrin àwọn ènìyàn.

10Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ, tí ó dé ọ̀run; òtítọ́ Rẹ tàn dé àwọ̀sánmọ̀.

10

11Gbígbéga ni ọ, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ; kí ògo Rẹ̀ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>