1Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòotọ́ ẹ̀yin ijọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ẹ̀yìn ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́ ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
2Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìsòdodo, Ọmọ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.
3Ní inú ìyá wọn wá, ni eniyàn búburú tí sìnà lojukan náà tí a ti bí wọn wọn a máa ṣèké.
4Ọ̀rọ̀ wọn dà bí ọ̀rọ̀ ejò, gẹ́gẹ́ bí ti sèbé tí ó dítí Rẹ̀, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara Rẹ̀ ni etí
5Tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atinilójú, bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
5
6Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run; ní ẹnu wọn ká ọ̀gan àwọn ọmọ kìnnìún, OLÚWA.
7Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń ṣàn lọ; nígbà tí ó bá fa ọfà Rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
8Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí Rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé bí ọmọ ti oṣu Rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí òòrùn.
8
9Kí ìkòkò yín kì o tó mọ̀ ìgbóná ẹ̀gún; ìbá tutù, ìbá ma jò, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10Olódodo yóò yọ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11Àwọn ènìyàn yóò wí pé, “lóòtọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo; lóòtọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”