1Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run; dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
2Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.
2
3Wòó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí! Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi Kìí se nítorí ìrékọja mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, OLÚWA.
4Èmí kò ṣe àìṣedédé kan, ṣíbẹ̀ wọ́n sáré, wọ́n ṣetán láti kọlù mi. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
5OLÚWA Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, dìde fún ara Rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀ èdè wí; Má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì.
5Sela
6Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọ́n ń gbó bí àwọn ajá, wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
7Kíyèsí ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu: wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn, wọn sì wí pé, “Ta ní ó le gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”
8Ṣùgbọ́n ìwọ, OLÚWA, yóò fi wọ́n rẹ́rin-ín Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè.
8
9Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ; nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
10Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.
10Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi. Yóò sì jẹ́ kí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gún lórí àwọn ọ̀tá ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi.
11Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, OLÚWA asà wa, kí àwọn ènìyàn mí má ba à gbàgbé. Nínú agbára Rẹ̀, jẹ́ kí wọ́n máa rìn kiri, kí ó sì Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn, ni ọ̀rọ̀ ètè wọn, kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn. Nítorí ẹ̀gàn àti èké tí wọn ń sọ,
13Pa wọn run nínú ìbínú, run wọ́n di ìgbà tí wọ́n kò ní sí mọ́. Nígbà náà ní yóò di mímọ̀ dé òpin ayé pé Ọlọ́run jọba lórí Jákọ́bù.
13Sela
14Wọ́n padà ní àsálẹ́, wọn ń gbó bí àwọn ajá wọ́n ń rìn ìlú náà káàkiri.
15Wọ́n ń rín kiri fún oúnjẹ wọn sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.
16Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára Rẹ, ń ó kọrin ìfẹ́ Rẹ ní òwúrọ̀; nítorí ìwọ ni ààbò mi, ibi ìsádì mi ní ìgbà ìpọ́njú.
16
17Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ; ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.