Ìwé Sáàmù 6:1-10 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú Rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú Rẹ

2Ṣàánú fún mi, OLÚWA, nítorí èmi ń ku lọ; OLÚWA, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.

3Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, OLÚWA, yóò ti pẹ́ tó?

3

4Yípadà, OLÚWA, kí ó sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ Rẹ tí kì í ṣákìí.

4

5Ẹnikẹ́ni kò sì rántí Rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú iṣà òkú?

6Agara ìkérora mi da mi tán; gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.

7Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.

7

8ⓐ Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí OLÚWA ti gbọ́ igbe mi.

9OLÚWA ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; OLÚWA ti gba àdúrà mi.

10Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>