Ìwé Sáàmù 60:1-12 BYB2014 - Bible AI

1Ìwọ tí kọ̀ wá sílẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká ìwọ ti bínú nísìnsín yìí, tún ara Rẹ yípadà sí wá.

2Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ; mú fífọ́ Rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mi.

3Ìwọ ti fi ìgbà ewu hàn àwọn ènìyàn Rẹ; Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wa gbọ́n-ọ́ngbọ́n-ọ́n.

3

4Àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ní ìwọ fi ọ̀págun fún kí a lè fíhàn nítorí òtítọ́.

4Sela

5ⓐ Fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́, kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.

6Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ Rẹ̀: “Ní ayọ̀, èmi ó pín ṣèkémù jáde èmi o sì wọ̀n àfonífojì ṣúkótù.

7Tèmi ni Gílíádì, tèmi sì ni Mánásè; Éfúráímù ni àsìbórì mi, Júdà sì ní ọ̀pá àṣẹ mi.

8Móábù ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Édómù ní mo bọ́ bàtà mi sí; lórí fìlísitinì ni mo kígbe ayọ̀.”

8

9Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì? Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Édómù?

10Kí ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?

11Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá, nítorí asán ní ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.

12Nípa Ọlọ́run ni a ó ní ìṣẹ́gun, yóò sì tẹ̀ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>