1Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; Tẹ́tí sí àdúrà mi.
2Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
3Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìsọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
3
4Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ Rẹ títí láé kí ń sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá Rẹ.
5Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run; Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ Rẹ̀.
5
6Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí o gùn, ọdùn Rẹ̀ fún ìrandíran.
7Kí o máa jọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ Rẹ̀ tí yóò máa ṣe ìtọ́ju Rẹ.
7
8Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ títí láé kí ń san ẹ̀jẹ́ mí ní ojoojúmọ́.