1Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ wá.
2Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; oun ní ààbò mi, a kí yóò sí mi ní pò padà.
2
3Ẹ̀yin ó ti máa rọ́lù ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀ àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
4Kìkì èró wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá Rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọn ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn nínú ọkàn wọn.
4Sela
5Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmí wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ.
6Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kí yóò sí mi nípò.
7Ìgbàlà mi àti ògo mí dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
8Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn Rẹ̀ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ní ààbò wa.
8
9Ní tòótọ́, asán ní àwọn ọmọ ènìyàn, èké si ni àwọn olóyè, wọn gòkè nínú ìwọ̀n bákan náà ni wọn fẹ́rẹ̀ jù asán lọ lápapọ̀ wọn jẹ èémí.
10Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnílára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ Rẹ̀ ń pọ̀ síi, má ṣe gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn.
10
11Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ní agbára
12ⓐ Pẹ̀lúpẹ̀lú, OLÚWA, tirẹ ni àánú nitorí ti iwọ san án fun olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ Rẹ̀.