1Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ní mo ń ṣàfẹ́rí Rẹ óùngbẹ́ Rẹ ń gbẹ ọkàn mi ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ ti ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi
2Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́ mo rí agbára àti ògo Rẹ.
3Nítorí ìfẹ́ Rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ.
4Èmi o yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ Rẹ.
5A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ.