Ìwé Sáàmù 64:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá

2Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

2

3Wọn pọ́n ahọ́n wọn bí idà wọn sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.

4Wọ́n tafà ní kọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀: wọ́n tafà sí lojijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

4

5Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú, wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹ́kun sílẹ̀ ní kọ̀kọ̀ wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”

6Wọ́n gbìmọ̀ àìsòdodo, wọn wí pé, “A wa ti parí èrò tí a gbà tán” lóòtọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

6

7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà; wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.

8Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.

8

9Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10Jẹ́ kí Olódodo kí o yọ̀ nínú OLÚWA yóò sì rí ààbò nínú Rẹ̀ Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ni àyà yóò máa yìn ín.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>