Ìwé Sáàmù 65:1-13 BYB2014 - Bible AI

1Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ni Síónì; sì ọ ni a o mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

2Ìwọ tí o ń gbọ́ àdúrà, gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ Rẹ.

3Ọ̀ràn àìṣedédé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni! Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò

4Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ Rẹ! A tẹ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé Rẹ, ti tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ.

4

5Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohùn ìyanu ti òdodo, Ọlọ́run olùgbàlà wa, ìrètí gbogbo òpin ayé àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,

6Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára Rẹ tí ó di ara Rẹ̀ ní àmùrè agbára

7Ẹni tí ó mú ríru omi òkun dákẹ́ ríru ariwo omi wọn, àti gìdìgìdì àwọn ènìyàn

8Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù agbára Rẹ̀: ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ̀ yọ ìwọ pé orin ayọ̀ jáde.

8

9Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin; ìwọ mú ní ọ̀rọ̀ púpọ̀. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún fún omi láti pèsè ọkàn fún àwọn ènìyàn, nítorí ibẹ̀ ní ìwọ ti yàn án.

10Ìwọ fi ìrinmi sí aporo Rẹ ìwọ tẹ́ ògúlùtù Rẹ; ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ Rẹ rọ̀ o sì bùkún ọ̀gbìn Rẹ.

11Iwọ fi oore Rẹ de ọdún ni adé, ọ̀rá ń kan ni ipa-ọ̀nà Rẹ

12Pápá-tútù ni ihà ń kán: àwọn òkè kékèké fi ayọ̀ di ara wọn ni àmùrè.

13Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà, ni asọ; àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀, wọn hó fún ayọ̀, wọn ń kọrin pẹ̀lú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>