Ìwé Sáàmù 66:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, gbogbo ayé!

2Ẹ kọrin ọ̀lá orúkọ Rẹ̀; Ẹ fún un ní ìyìn, ògo,

3Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé, ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ Rẹ̀! Nípa ọ̀pọ̀ agbára Rẹ ni àwọn ọ̀tá Rẹ yóò fi sìn ọ́.

4Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ; wọn ń kọrin ìyìn sí ọ, wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ.”

4Sela

5Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe, Iṣẹ́ Rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!

6O yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú Rẹ.

7O ń jọba títí láé nípa agbára Rẹ̀, ojú Rẹ̀ ń wò orílẹ̀ èdè kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga.

7Sela

8Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn, jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohun ìyìn Rẹ̀;

9O ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí o yẹ̀

10Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, Dan wa wò; ìwọ dán wa bí a tí ń Dan fàdákà wo

11Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹ̀rù lé ẹ̀yìn wa

12Ìwọ mú àwọn ènìyàn gun wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

12

13Èmi ó wá sí tẹ́ḿpìlì Rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ

14Ẹ̀jẹ́ ti ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìsòro.

15Èmi o sun ẹbọ ọlọ́ràá sí ọ àti ẹbọ ọ̀rá àgbò; èmi o rú akọ màlúù àti ewúrẹ́.

15Sela

16Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù OLÚWA; ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.

17Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i: Ìyìn Rẹ̀ wà ní ẹnu mi.

18Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, OLÚWA kì yóò gbọ́ ohùn mi;

19Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ o ti gbọ́ ohun mi nínú àdúrà.

20Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ Rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>