1Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí o sì bùkún fún wa kí ó sì jẹ́ kí ojú Rẹ̀ tàn yí wa ká,
2kí ọ̀nà Rẹ̀ le di mímọ̀ ní ayé, ìgbàlà Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.
3Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí o yìn ọ!
4Kí orílẹ̀ èdè kí o yọ̀, kí o sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn ìwọ si jọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
5Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́.