Ìwé Sáàmù 69:1-36 BYB2014 - Bible AI

1Gbàmí, Ọlọ́run, nítorí omi tí kún dé ọrùn mi.

2Mo ń rì nínú ìrà jínjìn, níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé. Mo ti wá sínú omi jínjìn; ìkún omi bò mí mólẹ̀.

3Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́; ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú, nígbà ti èmi dúró de Ọlọ́run mi

4ⓐ Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí wọn ju irun orí mi; lọ púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí, àwọn tí ń wá láti pa mí run A fi ipá mú mi láti san ohun tí èmi kò jí.

4

5Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run; ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú Rẹ.

6Má ṣe dójú tì àwọn tí ó ní ìrètí nínú Rẹ nítorí mi, OLÚWA, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun; Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7Nítorí Rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn, ìtìjú sì bo ojú mi.

8Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi; àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

9ⓑ Nítorí ìtarà ilé Rẹ jẹ mí run, àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

10Nígbà tí mo sunkún tí mo sì ń fi ààwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

11Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà, àwọn ènìyàn ń pòwe mọ́ mi.

12Àwọn tí ó jòkòó ní ẹnu ibodè ń bú mi, mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

12

13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi n gbàdúrà mi sí OLÚWA, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi Rẹ, dá mí lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà Rẹ tí ó dájú.

14Gbá mí kúrò nínú ẹrẹ̀, Má ṣe jẹ́ kí ń rí; gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí o korìíra mi, kúrò nínú ibú omi.

15Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu Rẹ̀ dé mọ́ mi.

16Dá mí lóhùn, OLÚWA nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ; nínú ọ̀pọ̀ àánú Rẹ yípadà sí mi.

17Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ: yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

18Súnmọ́ tòsí kí ó sì gbà mí là; rà mí padà nítorí àwọn ọ̀ta mi.

18

19Ìwọ tí mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá; Gbogbo àwọn ọ̀ta mi wà níwájú Rẹ̀.

20Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́ wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí, mo ń wá olùtùnú, Ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

21Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi, àti ní òungbẹ mi, wọn fi ọtí kíkan fún mi.

21

22Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó dí ìkẹ́kùn ni iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23Kí ojú wọn kií ó ṣókùnkùn kí wọ́n má ṣe ríran, kí eyín wọn di títẹ̀ títí láé.

24ⓒ Tú ìbínú Rẹ jáde sí wọn; kí ìbínú gbígbóná Rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

25ⓓ Kí ibùjókòó wọn di ahoro; kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù, àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe

27Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn; Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà Rẹ.

28ⓔ Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè kí á má kà wọn pẹ̀lú àwọn olódodo.

28

29Ṣùgbọ́n talákà àti ẹni-ìkáánú ni èmí, Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà Rẹ gbé mi lékè.

29

30Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga èmi yóò fí ọpẹ́ gbé orúkọ Rẹ̀ ga.

31Eléyìí tẹ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo Rẹ̀ àti bàtà Rẹ̀.

32Àwọn òtòsì yóò rí wọn yóò sì yọ̀: Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yin yóò sì wà láàyè!

33OLÚWA, gbọ́ ti aláìní kí o sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

33

34Kí ọ̀run àti ayé yìn ín, òkun àti àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀,

35Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Síónì là yóò sì tún àwọn ìlú Júdà wọ̀nyí kọ́. Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa níi ni ilẹ̀ ìní

36Àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún Rẹ̀, àwọn ti ó fẹ́ orúkọ Rẹ ní yóò máa gbé inú Rẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>