Ìwé Sáàmù 7:1-17 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú Rẹ; gba mí là kí o sì tú mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,

2kí wọn ó má bá à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún wọn a ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gba mí.

2

3OLÚWA Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi

4Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi tí mo ja ọ̀ta mí lólè láìnídìí:

5Nígbà náà jẹ́ kí ọ̀ta mi le mi kí wọn sì mú mi; jẹ́ kí òun kí ó tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀ kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku.

5Sela

6Dìde, OLÚWA, nínú ìbínú Rẹ; dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀ta mi. Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.

7Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yí ká. Jọba lórí wọn láti òkè wá;

8Jẹ́ kí OLÚWA ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. ṣe ìdájọ́ mi, OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.

9ⓐ Ọlọ́run Olódodo, Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn, tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.

9

10Aṣà mi ní Ọlọ́run tí ó gajù, ẹni tí ń dáàbò bo àwọn ẹni gíga nípa ti èmi.

11Ọlọ́run ni onídàájọ́ tòótọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrúnú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.

12Bí kò bá yípadà, òun yóò pọ́n idà Rẹ̀ mú ó ti fa ọrun Rẹ̀ le ná ó ti múra Rẹ̀ sílẹ̀

13Ó ti pèṣè ohun ìjà ikú sílẹ̀; ó ti pèṣè ọfà iná sílẹ̀.

13

14Ẹni tí ó lóyún ohun búburú, tí ó sì lóyùn wàhálà ó bí èké jáde.

15Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde jìn sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.

16Wàhálà tí ó fà padà sórí Rẹ̀; Ìwà ipá Rẹ̀ padà sórí ara Rẹ̀.

16

17Èmi ó fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí òdodo Rẹ̀ Èmi ó kọrin ìyìn sí OLÚWA tí ó ga jùlọ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>