Ìwé Sáàmù 70:1-5 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, OLÚWA, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

2Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi kí a dojú tì wọ́n, kí wọn sì dààmú; kí àwọn tó ń wá ìparun mi yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.

3Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Áà! Áà!”

4Ṣùgbọ́n kí àwọn tí o ń wà ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa Rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà Rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

4

5Ṣíbẹ̀ mo jẹ́ òtòsì, mo sì jẹ́ aláìní; wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùtúsílẹ̀ mi; OLÚWA, má ṣe dúró pẹ́.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>