Ìwé Sáàmù 71:1-24 BYB2014 - Bible AI

1Nínú Rẹ̀, OLÚWA, ní mo ní ààbò; Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

2Gbà mí kí ó sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo Rẹ; kọ etí Rẹ sími kí o sì gbà mí.

3Jẹ́ àpáta ààbò mi, nibi tí èmi lè máa lọ pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti asà mi.

4Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú, ní ọwọ́ aláìsòdodo àti ìkà ọkùnrin.

4

5Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, OLÚWA Ọlọ́run, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mí láti ìgbà èwe

6Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mu mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ títí láé

7Mo di ẹni ìyanu fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8Ìyìn Rẹ̀ kún ẹnu mi, o ń sọ ti ọlá Rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo.

8

9Má ṣe ta mí nù ni ọjọ́ ogbó mi Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́

10Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ òdì sí mi àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀

11Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa Rẹ̀ kí ẹ sì mu nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”

12Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run; wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti rànmí lọ́wọ́.

13Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù bò àwọn tí ń wá ìpalára mi.

13

14Ṣùgbọ́n ní tèmí, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi; èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sì i.

15Ẹnu mí yóò sọ nípa ti òdodo Rẹ, ti ìgbàlà Rẹ ni gbogbo ọjọ́ lóòtọ́, èmi kò mọ́ iye Rẹ̀.

16Èmi ó wá láti wá kéde agbára OLÚWA Ọlọ́run; èmi ó kéde òdodo Rẹ̀ nìkan.

17Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ tí kọ́ mí títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.

18Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí ẹnu di arúgbó tán tí mo sì hewú, Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run títí tí èmi o fi ipá re han ìran yìí àti agbára Rẹ fún gbogbo àwọn ará ẹ̀yìn, sọ ti agbára sí ìran tí ń bọ̀ agbára Rẹ̀ fún àwọn tí yóò wá.

18

19Ọlọ́run, Òdodo Rẹ̀ dé ọ̀run, ìwọ tí ó ti ṣe ohun ńlá Ta ni, Ọlọ́run, tí o dà bí i Rẹ?

20Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí o pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀

21Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní hà gbogbo.

21

22Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ Rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

23Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn nígbà tí mo bá kọrín ìyìn sí ọ: èmi, ẹni tí o ràpadà.

24Ahọ́n mí yóò sọ ti òdodo Rẹ ní gbogbo ọjọ́, fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>