1Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,ọmọ aládé ni ìwọ fi òdodo Rẹ fún
2Yóò ṣe ìdàjọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú òdodoyóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn talákà Rẹ
3Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyànàti òkè kékèké nípa òdodo
4Yóò dábò bò àwọn tí a pọ́n lójú láàrin àwọn ènìyànyóò gba àwọn ọmọ aláìní;yóò sì fa àwọn aninilára ya.
4
5Àwọn òtòsì àti aláìníyóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,yóò ti pẹ́ tó,láti ìran díran.
6Yóò dàbí òjò tí o ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
7Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ Rẹ̀ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;títí tí oṣùpá kò fi ní sí mọ́
7
8Yóò máa jọba láti òkun dé òkunàti láti odò títí dé òpin ayé.
9Àwọn tí ó wà ní ihà yóò tẹríba fún unàwọn ọ̀ta Rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10Àwọn ọba Táṣíṣì àti tí erékùṣùwọn yóò mú ọrẹ wá fún un;àwọn ọba Ṣéba àti Síbàwọn o mú ẹ̀bùn wá fún-un.
11Gbogbo ọba yóò tẹríba fún-unàti gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sìn ín.
11
12Nítorí yóò gba àwọn aláìnínígbà tí ó bá ń ké,tálákà àti ẹní tí kò ni olùrànlọ́wọ́.
13Yóò káànú àwọn aláìlera àti aláìníyóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipánítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú Rẹ.
14
15Yóò sì yè pẹ́!A ó sì fún un ní wúrà Ṣébà.Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún-un nígbà gbogbokí a sì bùkún fún-un lójojúmọ́.
16Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;ní orí òkè ni kí ó máa dàgbàkí èso Rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lébánónìyóò máa gbá yìn-ìn bí koríko ilẹ̀.
17Kí orúkọ Rẹ̀ kí o wà títí láé;orúkọ Rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọn bí òòrùn yóò ti pẹ́ tó;wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nipaṣẹ̀ Rẹ.Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
17
18Olùbùkún ní OLÚWA Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́li,ẹnìkan ṣoṣo tí ó n ṣe ohun ìyanu.
19Olùbùkun ni orúkọ Rẹ tí ó lógo títí láé;kí gbogbo ayé kún fún ògo Rẹ.Àmín àti Àmín.