1Nítòótọ̀ Ọlọ́run dára fún Ísírẹ́lì, fún àwọn ọlọ́kàn funfun.
2Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
3Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣeféfé nígbà tí mo bá rí ọlá àwọn ènìyàn búburú.
3
4Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára.
5Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ si ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlomíràn.
6Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ìpá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
7Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìsòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdiwọ̀n
8Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀ òdì níti ìnilára, wọn ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
9Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run ahọ́n wọn gba ipò ayé.
10Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀? Ọ̀gá ògo ha ní ìmọ̀ bí?”
12Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí ènìyàn asán, wọn ń pọ̀ ní ọrọ̀.
12
13Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́sẹ̀.
14Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí níyà ní gbogbo òwúrọ̀.
14
15Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” Èmi ó ṣẹ̀sí ìran àwọn ọmọ Rẹ̀.
16Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, O jẹ́ ìnilára fún mi.
17Tí tí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi,
18Lótítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọn pátapáta!
20Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, OLÚWA, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.
21Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi sì korò,
22Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní ìwájú Rẹ.
22
23Ṣíbẹ̀ mo wà pẹ̀lú Rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24Ìwọ fi ìmọ̀ràn Rẹ tọ́ mi ní kẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo
25Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn Rẹ.
26Ara mi àti ọkàn mi leè kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé.
26
27Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run; tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ Rẹ
28Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run Èmi ti fi OLÚWA Ọlọ́run ṣe ààbò mi; Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ.