1Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé? Èéṣe tí ìbínú Rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá Rẹ?
2Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́, ẹ̀yà ilẹ̀ ìní Rẹ, tí ìwọ ti ràpadà Òkè Síónì, níbi tí ìwọ ń gbé.
3Yí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ padà sí ìparun ayérayé wọn, gbogbo ìparun yìí tí ọ̀ta ti mú wá sí ibi mímọ́.
4Àwọn ọ̀tá Rẹ ń bú ramú-ramù láàrin ìja ènìyàn Rẹ, wọ́n ń gbé Àṣìá wọn sókè fún àmì;
5Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké Rẹ̀ sókè láti gé igi igbó dídí.
6Ṣùgbọ́n nìsìnsìn yìí iṣẹ́ ọnà fínfín ní wọn fi àáké òòlù wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà
7Wọ́n sun ibi mímọ́ Rẹ̀ lulẹ̀ wọ́n ba ibùgbé orúkọ Rẹ̀ jẹ́
8Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátapáta!” Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
9A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan; kò sí wòlíì kankan ẹnìkan kan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
9
10Àwọn ọ̀ta yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run? Àwọn ọ̀ta yóò ha ba orúkọ Rẹ jẹ́ títí láé?
11Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ Rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ? Mú-un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ Rẹ kí o sì run wọ́n!
12Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́; ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
13Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára Rẹ; Ìwọ fọ́ orí àwọn abàmì ẹ̀dá nínú omi
14Ìwọ fọ́ orí Lefiatani túútúú, o sì fi se oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá ti ń gbé inú ìjù Tìrẹ ní ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú; ìwọ fi ìdí òòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15Iwọ ya orísun omi àti iṣàn omi; Ìwọ mú kí odò tó ń ṣàn gbẹ
16Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú; ìwọ yà oòrùn àti òsùpá.
17Ìwọ pààlà etí ayé; Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
18Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn Rẹ, OLÚWA bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ Rẹ jẹ́.
19Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà Rẹ fún ẹranko ìgbẹ́ búburú; Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn Rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20Bojúwo májẹ̀mu Rẹ, nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú jẹ́ kí àwọn aláìní àti talákà yin orúkọ Rẹ.
21
22Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara Rẹ̀ rò; rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn Rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23Má ṣe gbàgbé ohun àwọn ọ̀tá Rẹ, bíbú àwọn ọ̀tá Rẹ, tí ó ń pọ̀ síi nígbà gbogbo.