Ìwé Sáàmù 75:1-10 BYB2014 - Bible AI

1A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ Rẹ̀ súnmọ́ tòsí; àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu Rẹ.

2Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀; Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.

3Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì, Èmi ni mo di òpó Rẹ̀ mú ṣinṣin.

4Èmí wí fún àwọn agbéraga pé Ẹ má ṣe gbéraga mọ́; àti sí ènìyàn búburú; Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.

5Ẹ máa ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run; ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

5

6Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé kò ti ìlà-oòrùn wá tàbí ní ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúsù wá.

7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdajọ́; Òun Rẹ̀ ẹnìkan sílẹ̀, ó sí ń gbé ẹlòmíràn ga.

8Ní ọwọ́ OLÚWA ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pòpọ̀ mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àti búburú ayé gbogbo mú u sílẹ̀ pátapáta.

8

9Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn Rẹ títí láé; Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jákọ́bù (Ísírẹ́lì)

10Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>