Ìwé Sáàmù 76:1-12 BYB2014 - Bible AI

1Ní Júdà ni a mọ Ọlọ́run; orúkọ Rẹ̀ sì lágbára ní Ísírẹ́lì

2Àgọ́ Rẹ̀ wà ní Sálẹ́mù, ibùgbé Rẹ̀ ní Síónì.

3Níbẹ̀ ní o ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun.

3Sela

4Iwọ ni ògo àti ọlá Ju òkè-ńlá íkogun wọ̀nyìí lọ.

5Àwọn akíkanjú ọkùnrin A kó àwọn akíkanjú ogun ní ìkógun wọn sún oorun ìgbẹ̀yìn wọn; kò sí ọ̀kan nínú àwọn ajagun tó lè gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè.

6Ní ìfìbú Rẹ, Ọlọ́run Jákọ́bù, àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dúbúlẹ̀ ṣíbẹ̀.

7Ìwọ nìkan ni o yẹ kí a bẹ̀rù. Ta ló lé dúró níwájú Rẹ nígbà tí ìwọ bá ń bínú?

8Ìwọ ń ṣe ìdàjọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ ẹ́:

9Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnílára ilẹ̀ náà.

9Sela

10Lóòtọ́, ìbínú Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ, ẹni tí ó yọ nínú ìbínú Rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara Rẹ ni àmùrè.

10

11Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí OLÚWA Ọlọ́run Rẹ kí o sì mú-un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yíi ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí o tọ́ láti bẹ̀rù.

12Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò; àwọn ọba ayé sì n bẹ̀rù Rẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>