Ìwé Sáàmù 77:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.

2Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá OLÚWA; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ láti tùú nínú.

2

3Èmi rántí i Rẹ, Ọlọ́run, mo sì kẹ́dùn; mo ṣe àroyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì.

3Sela

4Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fí ojú ba òorùn, mo dàámú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.

5Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì; ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;

6Mo rántí orin mi ní òru. Èmi ń bá àyà mí sọ̀rọ̀, ọkàn mí sì ń ṣe àwárí jọjọ.

6

7OLÚWA yóò ha kọ̀ títí láé? Kí yóò ha ṣe ojú rere Rẹ̀ mọ́

8Ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ àti àánú Rẹ̀ tí kú lọ láéláé? Ìlérí Rẹ̀ ha kùnà títí ayé?

9Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú Rẹ̀, ó ha sé ojú rere Rẹ̀ mọ́?

9Sela

10Èmí wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.

11Èmi ó rántí iṣẹ́ OLÚWA: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.

12Èmi ṣàṣárò lórí iṣẹ́ Rẹ gbogbo pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára Rẹ.

12

13Ọlọ́run, Ọ̀nà Rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ní ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?

14Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára Rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.

15Pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jákọ́bù àti Jósẹ́fù.

15Sela

16Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.

17Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọ̀sánmọ̀ fí àrá dáhùn; ọfà Rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú

18Àrá Rẹ̀ ni a gbọ ní ibi ìjì, ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé; ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.

19Ìpa Rẹ̀ gba òkun, ọ̀nà Rẹ ń bẹ nínú òkun, Ọ̀nà la omi alágbára kọ́já ipa Rẹ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹṣẹ̀ Rẹ̀.

20Ó tọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mósè àti Árónì.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>