1Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi; tẹ́tí Rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2ⓐ Èmi ó la ẹnu mi ní òwe èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
3Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
4Àwa kí yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífí ìyìn OLÚWA, àti ipa Rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀.
5Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jákọ́bù o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Ísírẹ́lì, èyí tí ó páláṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
6Nítorí náà àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí i bí tí yóò dìde ti wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
7Nígbà náà ni wọn o fi ìgbẹ̀kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn o pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́.
8Wọn ò ní dàbí àwọn baba ńlá wọn ìran aláyà líle àti ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn wọn kò sòòtọ̀ si oloore.
8
9Àwọn ọkùnrin Éfúráímù, tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun, wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun
10Wọ́n kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin Rẹ̀
11Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe, àwọn ìyanu tí ó ti fi hàn wọ́n.
12O ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní agbégbé Síónì
13O pín òkun níyà, ó sì mú wọn kọjá ó mù kí ó nà dúró bá ebè
14Ní ọ̀ṣán ó fi ìkúùku àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú, ìmọ̀lẹ̀ ìná.
15Ó sán àpáta ní ihà ó si fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16O mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi sìṣsàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò
17Wọ́n sì tún tẹ̀ṣíwájú láti dẹ́sẹ̀ sí i ní ìsọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá ògo ní àgìnjú.
18Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19Wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ tábìlì ní aṣálẹ̀?
20Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì ṣàn lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèṣè ẹran fún àwọn ènìyàn Rẹ̀”
21Nígbà tí OLÚWA gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná Rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jákọ́bù, ìbínú Rẹ̀ sì rú sí Ísírẹ́lì,
22Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́ wọn kò sí gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà Rẹ̀
23Ṣíbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run ó sì sí ilẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24ⓑ Ó rọ mánà fún àwọn ènìyàn láti jẹ, ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run
25Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn ańgẹ́lì; o fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó
26Ó sṣ́ afẹ́fẹ́ ìlà òòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúsù wá nípa agbára Rẹ̀.
27Ó rọ ọ̀jọ̀ ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyànrìn etí òkun
28Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn.
29Wọn jẹ, wọ́n sí yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
30Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọ́n fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
31Ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì bolẹ̀.
31
32Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọn ń sá síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́
33O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà.
34Nígbà kígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kirì; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.
35Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn; wí pé Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn
36Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n-ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n wọ́n fí ahọ́n wọ́n purọ́ fún un;
37ⓒ Ọkàn wọn kò sòtítọ́ si i, wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú Rẹ̀.
38Ṣíbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedédé wọn jìn òun kò sì pa wọn run nígbà kí ì gbà ló ń dá ìbínú Rẹ̀ dúró kò sì rú ìbínú Rẹ̀ sókè
39Ó ránti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò le padà.
39
40Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ síi ní ihà wọn mú-un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!
41Síwájú àti síwájú wọn dán Ọlọ́run wò; wọ́n mú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì bínú.
42Wọ́n kò rántí agbára Rẹ̀: ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára,
43Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ hàn ní Éjíbítì, àti iṣẹ́ àmì Rẹ ni ẹkùn Sáónì
44Ó ṣọ omi wọn dí ẹ̀jẹ̀; wọn kò le mú láti odò wọn.
45Ó rán ọ̀wọ́ ẹṣinṣin láti pa wọ́n run, àti ọpọlọ tí ó bá wọn jẹun.
46Ó fi ọkà wọn fún láńtata àwọn irè oko wọn fún eṣú
47Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sìkàmore wọn jẹ́
48Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná
49Ó mú kíkorò ìbínú Rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ikáánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán ańgẹ́lì apanirun sí wọn.
50Ó pèṣè ipa fún ìbínú Rẹ̀ òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-àrùn
51Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Éjíbítì Olórí agbára wọn nínú àgọ́ Ámù
52Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran; ó sọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú ihà.
53Ó dáàbòbò wọ́n dáadáa, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
54Bákan náà ní ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ Rẹ òkè tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ tí gbà
55Ó lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú wọn ó sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní; ó mú àwọn ẹ̀yà Íṣírẹ́lì jókòó ní ilẹ̀ wọn.
55
56Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo; wọn kò pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́.
57Gẹ́gẹ́ bí baba wọn, wọn jẹ́ aláìsòdodo gẹ́gẹ́ bi ọrun ẹ̀tàn
58Wọ́n bí nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn; wọn rú owú Rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn
59Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi; ó kọ Ísírẹ́lì pátapáta.
60Ó kọ àgọ́ Ṣílò sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn.
61Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára Rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn, dídán ògo Rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
62Ó fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé idà lọ́wọ́, ó sì bínú sí àwọn ohun ìní Rẹ̀.
63Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn, àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
64A fi àlùfáà wọn fún idà, àwọn opó wọn kò sì le è sunkún.
64
65OLÚWA sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jù kúrò nínú ìraníyè ọtí.
66Ó kọlu àwọn ọta Rẹ̀ padà; ó fí wọn sínú ìtìjú ayérayé.
67Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Jósẹ́fù, kò sì yan ẹ̀yà Éfúráímù;
68Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Júdà, òkè Síónì, èyí tí ó fẹ́ràn.
69Ó kọ́ ibi mímọ́ Rẹ̀, ibí gíga, gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
70Ó yan Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀ ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
71Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́ Àgùntàn àwọn ènìyàn Rẹ̀ Jákọ́bù àti Ísírẹ́lì ogún un Rẹ̀.
72Dáfídì sì ṣọ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn; pẹ̀lú ọwọ́ òye ní ó fi darí wọn.