1OLÚWA, OLÚWA wa, orúkọ Rẹ̀ ti tó tóbi tó ní gbogbo àyé! Ìwọ ti gbé ògo Rẹ̀ ga ju àwọn ọ̀run lọ.
2ⓐ Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀ta Rẹ, láti pa àwọn ọ̀ta àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
2
3Nígbà tí mo ro ọ̀run Rẹ, iṣẹ́ ìka Rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa Rẹ̀, ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú Rẹ̀?
5Ìwọ ṣeé ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju ẹ̀dá ọ̀run lọ ìwọ sì dée ní adé ògo àti ọlá.
5
6Ìwọ mu-un jọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ; ìwọ si fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀:
7gbogbo ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, àti ẹranko ìgbẹ́,
8ẹyẹ ojú ọrun, àti ẹja inú òkun, àti ohun tí ń wẹ nínú ipa òkun.
8
9OLÚWA, OLÚWA wa, Orúkọ Rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!