Ìwé Sáàmù 80:1-19 BYB2014 - Bible AI

1Gbọ́ tiwa, ìwọ olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì; ìwọ tí ó darí Jósẹ́fù bí ọwọ́ ẹran; ìwọ tí o jòkòó lórí ìtẹ́ láàrin Kérúbù, tàn jáde

2Níwájú Éfúremù, Bẹ́ńjámínì àti Mánásè. Rú agbára Rẹ̀ sókè; wa fún ìgbàlà wa.

2

3Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bà lé gbà wá là

4OLÚWA Ọlọ́run, ìbínú Rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ?

5Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹ̀kún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́

6Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.

6

7Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú Rẹ tàn sí wa, kí a ba à le gbà wá là.

8Ìwọ mú àjàrà jáde láti Éjíbítì; ìwọ lé àwọn aláìkọlà jáde, o sì gbìn-ín.

9Ìwọ sí àyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu tọ gbòǹgbò jìnlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà.

10A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjijì Rẹ̀, ẹ̀ka Rẹ dàbí kédárì Ọlọ́run.

11O yọ ẹ̀ka Rẹ̀ sínú òkun, ọwọ́ Rẹ̀ sí odò ńlá nì.

11

12Èéṣe tí ìwọ fi wó odi Rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń sa èso Rẹ̀?

13Ìmọ̀do láti inú igbó ń bàá jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.

14Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ, Ọlọ́run! Bo jú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,

15Gbòngbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara Rẹ.

15

16A gé àjàrà Rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn Rẹ̀ ń ṣègbé.

17Jẹ́ kí ọwọ́ Rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ, ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbékalẹ̀ fún ara Rẹ.

18Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ; mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ Rẹ.

18

19Tún wa yípadà, OLÚWA Ọlọ́run; kí ojú Rẹ̀ kí o tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>