Ìwé Sáàmù 81:1-16 BYB2014 - Bible AI

1Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jákọ́bù!

2Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

3Ẹ fún ìpè ni oṣù tuntun àní nígbà ti a yàn; ní ọjọ́ àjọ wa ti ó ni ìrònú.

4Èyí ni àṣẹ fún Ísírẹ́lì, àti òfin Ọlọ́run Jákọ́bù.

5Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Jósẹ́fù nígbà tí ó la ìlẹ̀ Éjíbítì já níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

5

6Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúro ní èjìká yín, a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.

7Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Méríbà.

7Sela

8“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín, bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Ísírẹ́lì.

9Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrin yín; ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.

10Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run Rẹ, ẹni tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì. Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

10

11“Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi; Ísírẹ́lì kò ní tẹríba fún mi.

12Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

12

13“Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi bí Ísírẹ́lì yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,

14Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn kí ń sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!

15Àwọn tí ó kórìíra OLÚWA yóò tẹríba níwájú Rẹ̀. Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé

16Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ́ yín èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>