Ìwé Sáàmù 82:1-8 BYB2014 - Bible AI

1Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá, ó ṣe ìdájọ́ láàárin àwọn “ọlọ́run òrìṣà”:

2“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìsòdodo kí ó sì ṣe ojú ìṣájú sí àwọn ènìyàn búburú?

3Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba; ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.

4Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní; gbà wọ́n kùró lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

4

5“Wọn kò mọ̀ ohunkankan, wọn kò lóye ohunkankan. Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn; a ni gbogbo ìpínlẹ̀ ayé.

5

6ⓐ “Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”; ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ ọ̀gá ògo jùlọ.’

7Ṣùgbọ́n ẹ̀yin o kú bí ènìyàn lásán; ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ aládé.”

7

8Dìde Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí gbogbo orílẹ̀ èdè ni ìní Rẹ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>