1Ọlọ́run, Má ṣe dákẹ́; Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ ẹ́.
2Wo bí àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ, bi àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
3Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn Rẹ; wọn gbìmọ̀ lòdì sí àwọn tí ó fẹ.
4Wọn wí pé, “wá,” ẹ jẹ́ kí a pa wọn run bí orílẹ̀ èdè, kí orúkọ Ísírẹ́lì ma bá a sí ní ìrántí mọ́.
4
5Wọn gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan; wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
6Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ara Íṣímaélì, tí Móábù àti ti Hágárì
7Gébálì, Ámónì àti Ámálékì, Fílítísitíà, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tirẹ̀.
8Áṣurí pẹ̀lú tí darapọ̀ mọ́ wọn láti ràn àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́.
8Sela
9Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Mídíánì bí o ti ṣe sí Sísérà àti Jábínì ní òdò Kíṣíónì,
10Ẹni tí ó ṣègbé ní Éndórí tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
11Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orébù àti Séébù, àwọn ọmọ aládé wọn bí Ṣébà àti Sálmúnà,
12Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní Ẹni pápá oko tútù Ọlọ́run.”
12
13Ìwọ Ọlọ́run, Ṣe wọn bí ààjà, bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14Bí ìna ti i jó ìgbẹ́ ìgbó àti bí ọ̀wọ́ iná ti ń mú òkè-ńlá gbiná,
15Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle Rẹ lépa wọn ja wọn lójú pẹ̀lú ìjì Rẹ
16fi ìtìjú kún ojú wọn kí àwọn ènìyàn báà lè ṣe àfẹ́rí orúkọ Rẹ àti kí o fí ìjì líle Rẹ dẹ́rùbà ìwọ OLÚWA.
16
17Jẹ́ kí ojú kí ó ti wọn, kí wọ́n sì dáámù láéláé kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ OLÚWA: pé ìwọ níkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.