Ìwé Sáàmù 84:1-12 BYB2014 - Bible AI

1Ibùgbé Rẹ̀ ti lẹ́wà tó, OLÚWA Olódùmarè!

2Ọkàn mí ń fà nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòùngbẹ fún àgbàlá OLÚWA àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.

2

3Nítòotọ́ ologóṣẹ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara r, níbi tí yóò máa pá ọmọ Rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ Rẹ, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

4Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé Rẹ; wọn o máa yìn ọ́ títí láé.

5Ìbùkún ní fún àwọn tí agbára wọn wà nínú Rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

6Àwọn tí ń la àfonífojì omije lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;

7Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Síónì.

7

8Gbọ́ àdúrà mi, OLÚWA Ọlọ́run Alágbára; tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jákọ́bù.

9Wo àsà wa, Ọlọ́run; fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òroro Rẹ.

9

10Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin Rẹ ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ; èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi ju láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11Nítorí OLÚWA Ọlọ́run jẹ́ òòrun àti àṣà; OLÚWA fúnni ní ojúrere àti ọlá; kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn dádúró fún àwọn tí o rin ní aílábùkù.

11

12OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>