1Ìwọ fi ojú rere han fún ilé Rẹ, OLÚWA; ìwọ mú ohun ìní Jákọ́bù bọ̀ sí pò.
2Ìwọ dárí àìṣedédé àwọn ènìyàn Rẹ̀ jìn ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
2Sela
3Ìwọ fi àwọn ìbínú Rẹ sápá kan ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná Rẹ.
4Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa, kí o sì yí ìbínú Rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
5Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé? Ìwọ yóò ha mú ìbínú Rẹ pẹ́ yìí gbogbo ìran ká?
6Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́, pé kí àwọn ènìyàn Rẹ lè yọ nínú Rẹ?
7Fi ìfẹ́ Rẹ tí kò le e kùnà hàn wá, OLÚWA, Kí o sì fún wa ní ìgbàlà Rẹ.
7
8Èmi ó gbọ́ ohun tí OLÚWA Ọlọ́run yóò wí; ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, àní ẹni mímọ́ Rẹ̀: Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmòye.
9Nítòótọ́ ìgbàlà Rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀, pé kí ògo Rẹ̀ kí ó le gbé ní ilẹ̀ wa.
9
10Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀; òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá òdodo sì bojúwolẹ̀ láti ọ̀run.
12OLÚWA yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́, ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè Rẹ̀ jáde.
13Òdodo ṣíwájú Rẹ lọ o sì pèṣè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ Rẹ̀.