1Gbọ́, OLÚWA, kí o sì dà mí lóhùn, nítorí mo jẹ́ talákà àti aláìní.
2Dáàbòbò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ: ìwọ ní Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ Rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
3Ṣàánú fún mi, OLÚWA, nítorí èmi ń pe ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
4Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ Rẹ, nítorí ìwọ, OLÚWA, ní mo gbé ọkan mí sókè sí.
4
5Ìwọ ń daríjì, ìwọ sì dára, OLÚWA, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn ti ń ké pè ọ́,
6Gbọ́ àdúrà mi, OLÚWA; tẹ́tí sí ẹkún fún àánú.
7Ní ọjọ́ ipọ́njú mi èmi yóò pe ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mí lóhùn.
7
8Nínú àwọn òrìṣà kò sì ẹni tí ó dà bí Rẹ, OLÚWA: kò sí àwọn iṣẹ́ tí a le fi wé tìrẹ.
9Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ dá yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú Rẹ, OLÚWA; wọn o mú ògo wà fún orúkọ Rẹ̀.
10Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ si ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ní Ọlọ́run.
10
11Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, OLÚWA, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ Rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ Rẹ.
12Èmi o yìn ọ, OLÚWA Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkan mi; èmi o fògo fún orúkọ Rẹ títí láé
13Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ̀ si mi; ìwọ ti gba mí kúrò nínú ọ̀gbun ìsà okú.
13
14Àwọn onígbéraga ń dojú kọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ̀ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ pè.
15Ṣùgbọ́n ìwọ, OLÚWA, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16Yípadà sí mi kí ó sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn Rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọ̀kunrin ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ là.
17Fi àmi hàn mí fun rere, kí àwọn tí ó kóriíra mi le rí, ki ojú le tì wọ́n, nítorí iwọ ni ó ti tù mi nínú.