1Ó ti fi ìpilẹ̀ Rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
2OLÚWA fẹ́ràn ẹnu ọ̀nà Síónì ju gbogbo ibùgbé Jákọ́bù lọ
3Ohun ológo ni a sọ nípa Rẹ, ilú Ọlọ́run;
4“Èmi ó dárúkọ Rákábù àti Bábílónì láàrin àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Fílístínì pẹ̀lú, àti Tirẹ, pẹ̀lú Kúṣì yóò sọ pé, èyí ni a bí ni Síónì.”
5Nítòótọ́, tí Síónì ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyì í ni a bí nínú Rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá ògo ni yóò fìdí Rẹ̀ múlẹ̀.”
6OLÚWA yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Síónì.”
7Àti àwọn olorin àti àwọn ti ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú Rẹ.”