1OLÚWA, Ọlọ́run tí o gba mí là, ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
2Jẹ́ kí àdúrà mi kí o wá sí iwájú Rẹ; dẹ etí Rẹ̀ sí igbe mi.
2
3Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
4A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀ èmi dà bí ọkùnrin tí kò ni agbára.
5A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú, ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́, ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
5
6Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jínjìn, ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
7Ìbínú Rẹ ṣubú lé mi gidigidi; ìwọ ti fi àwọn ìjì Rẹ̀ borí mi.
8Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mí kúrò lọ́wọ́ mi ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn. A há mi mọ́, èmi kò sì lé è jáde;
9Ojú mi káànú nítorí ìpọ́njú.
9Mo kígbe pè ọ́, OLÚWA, ní gbogbo ọjọ́; mo na ọwọ́ mí jáde sí ọ.
10Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ hàn fún òkú? Àwọn òkú yóò ha dìde láti yín ọ́ bí?
11A ó ha fi iṣeun ifẹ́ Rẹ hàn ni ibojì bí: Tàbí òtítọ́ Rẹ ni ipò iparun?
12A ha le mọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ ní òkùnkùn bí àti òdodo Rẹ ní ìlà ìgbàgbé?
12
13Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, OLÚWA; ní òwúrọ̀ ní àdúrà mí wá sọ́dọ̀ Rẹ.
14OLÚWA, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú Rẹ pamọ́ fún mi?
14
15Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú; nígbà ti ẹ̀ru Rẹ ba ń bà mí, èmi di gbére-gbère
16Ìbínú Rẹ ti kọjá lára mi; ìbẹ̀rù Rẹ ti ge mi kúrò
17Ní gbogbo ọjọ́ ní wọn yí mi ká bí ìkún omi; wọ́n mù mí pátápátá.
18Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi; òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.