1Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ OLÚWA títí láé;pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ̀ òtítọ́ Rẹ láti ìran dé ìran.
2Èmi ó wí pé, ìfẹ́ Rẹ dúró títí láé,pe ìwọ gbe òtítọ́ Rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ.
2
3ⓐ Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mu pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mimo ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi.
4Èmi ó fi ìdí irú ọmọ Rẹ múlẹ̀ títí láéèmí ó sì máa gbe ìtẹ́ Rẹ ró láti ìran dé ìran”.
5Àwọn ọ̀run yóò mú yín ṣiṣẹ́ ìyanu Rẹ, OLÚWA,òtítọ́ Rẹ ní ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
6Ta ní ó wà ni ọ̀run ti a lè fi we OLÚWA?Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fi wé OLÚWA?
7Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọn bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;ó sì ní ibùyìn fún jú gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
8OLÚWA Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí Rẹìwọ jẹ́ alágbára, OLÚWA, òtítọ́ Rẹ sì yí ọ ká.
8
9Ìwọ ń darí ríru omi òkun;nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn pa rọ́rọ́.
10Ìwọ ni o ti ya Ráhábù pẹ́rẹpẹ̀rẹbí ẹni tí a pa;ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára Rẹtú àwọn ọ̀tá Rẹ ká.
11Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ tìrẹ:ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú Rẹ̀:ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12Gúṣù àti Àríwá ìwọ ní ó dá wọn;Taborí àti Hámónì ń fi ayọ̀ yìn orúkọ Rẹ.
13Ìwọ ní apá agbára;agbára ní ọwọ́ Rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ.
13
14Òdodo àti òtítọ́ ní ìpílẹ̀ ìtẹ́ Rẹ:ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ ṣíwájú Rẹ.
15Ìbùkún ní fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ igbe ayọ̀,tí ó ń rìn OLÚWA nínú ìmọ́lẹ̀ oju Rẹ.
16Wọn ń ṣògo nínú orúkọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,wọn ń yin òdodo Rẹ.
17Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;nípa ojúrere ni ìwọ wá ń ṣògo.
18Nítorí tí OLÚWA ni asà wa,ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
18
19Nígbà náà ní ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran sí àwọn olótítọ́ Rẹ, wí pé:“èmi tí gbé adé kálẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,èmi ti gbé ẹni tí a yan láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20ⓑ Èmi tí rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ní mo fi yàn án;
21Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú Rẹ̀a pá mí yóò sì fi agbára fún un.
22Àwọn ọ̀tá kí yóò borí Rẹ̀,àwọn ènìyàn búburú kì yóò Rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23Èmi yóò run àwọn ọ̀tá Rẹ níwájú Rẹèmi yóò lu àwọn tí ó kóríra Rẹ bolẹ̀
24Òtítọ́ mi àti ìdúróṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú Rẹàti ní orúkọ mi ní a ó gbé ìwo Rẹ ga.
25Èmi o gbé ọwọ́ Rẹ lórí òkunàti ọwọ́ ọ̀tún Rẹ lórí àwọn odo ńlá
26Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ní bàbá mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27ⓒ Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mí,Ẹni gíga jù àwọn ọba ayé.
28Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29Èmi o fi ìdí irú ọmọ Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,àti ìtẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
29
30“Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀tí wọ́n kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
31Tí wọn bá kọ ìlànà mití wọ́n kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
32Nígbà náà ni èmi o fì ọ̀gà bẹ irékọjá wọn wòàti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú ìná:
33Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ Rẹ,tàbí ṣẹ́ tán sí òtítọ́ mi.
34Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mí,tàbí kí èmi yí ọ̀rọ̀ tí o ti ẹnu mi jáde padà.
35Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;èmi kì yóò purọ́ fún Dáfídì.
36Irú ọmọ Rẹ yóò dúró títí láé,àti ìtẹ́ Rẹ̀ yóò dúró bí òòrùn níwájú mi.
37ⓓ A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run”.
37Sela
38Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti sá tì, ìwọ sì kórìíra;ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró Rẹ.
39Ìwọ tì sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ Rẹ di òfo;ìwọ tàbùkù adé Rẹ nínú ilẹ
40Ìwọ tí wo gbogbo àwọn odi Rẹ̀ìwọ sọ ibi gíga Rẹ̀ di ahoro.
41Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;o ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé e Rẹ̀
42Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá Rẹ̀ sókè;ìwọ mú gbogbo ọ̀tá Rẹ̀ yọ̀.
43Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà Rẹ̀ padà,ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.
44Ìwọ ti mú ògo Rẹ̀ kùnà,ìwọ si wó ìtẹ́ Rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.
45Ìwọ ti gé ọjọ́ èwé Rẹ̀ kúrú;ìwọ si fi ìtìjú bò ó
46Yóò ti pẹ́ tó, OLÚWA?Tí ìwọ ó ha fi ara Rẹ pamọ́ títí láé?Yóò ti pẹ́ to tí ìbínú Rẹ yóò máa jó bí iná?
47Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tónítorí asán ha ní ìwọ fi sẹ̀dá àwọn ènìyàn!
48Ta ni yóò wà láàyè tí kò ní rí ìkú Rẹ̀?Ta lo lé sa kúrò nínú agbára isà-òkú?
49OLÚWA, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àtijọ́ wà,tí ìwọ ti fi òtítọ́ Rẹ̀ búra fún Dáfídì?
50Rántí, OLÚWA, bí àti ń gan àwọn ìránṣẹ́ Rẹ;bí èmi ti gbà ní àyà mi láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,
51Ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá Rẹ gàn, OLÚWA,tí wọn gan ipaṣẹ̀ Ẹni àmì òróró Rẹ.