1Èmi o yìn ọ, OLÚWA, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; Èmi o sọ ti ìyanu Rẹ gbogbo.
2Inú mi yóò dùn èmi yóò sì yọ̀ nínú Rẹ; Èmi o kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
2
3Àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà; Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú Rẹ.
4Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú; ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ Rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
5Ìwọ ti bá orílẹ̀ èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run; Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
6Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀ta, Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu; Àní ìrántí wọn sì ti sègbé.
6
7OLÚWA jọba títí láé; ó ti gbé ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
8ⓐ Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àyé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
9OLÚWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10Àwọn tí ó mọ orúkọ Rẹ yóò gbà ọ́ gbọ́, èmi tàbí ìwọ, OLÚWA, kò kọ àwọn to ń wa a sílẹ̀.
10
11Kọ orin ìyìn sí OLÚWA, ti o ń jọba ní Síónì; kéde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ohun tí o ṣe.
12Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí; òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
12
13OLÚWA, wo bí àwọn ọ̀ta ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu ọ̀nà ikú,
14Kí èmi kí o lè sọ ti ìyìn Rẹ ni ẹnu ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Síónì àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà Rẹ.
15Àwọn orílẹ̀ èdè ti jìn sí kòtò ti wọn ti gbẹ́; ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16A mọ OLÚWA nípa òdodo Rẹ̀; àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a ò ní gbàgbé láéláé, ìrètí àwọn ti ó talakà lójú kí yóò ṣègbé láéláé.
18
19Dìde, OLÚWA, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí; Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀ èdè ni iwájú Rẹ.
20Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, OLÚWA; jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n.