Ìwé Sáàmù 90:1-17 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìrán dé ìran.

2Kí a to bí àwọn òkè nla àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

2

3Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀, wí pé “padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn”.

4ⓐ Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú Rẹ, bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.

5Ìwọ gbá ènìyàn dánù nínú oorun ikú; wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.

6Lótìítọ́ ní òwúrọ́ ó yọ tuntun ní àsálẹ́ ní yóò gbẹ tí yóò sì Rẹ̀ dànù.

6

7A pa wá run nípa ìbínú Rẹ nípa ìbínú Rẹ ara kò rọ̀ wá.

8Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú Rẹ, àti ohun ìkọ̀kọ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ,

9Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú Rẹ; àwa n lo ọjọ wá lọ bí àlá ti a ń rọ́.

10Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún: wá, tí ó sì ṣe pé nipa agbára tí wọn bá tó ọgọrìn ọdún agbára wọn làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni nítorí pé a kò ni gé e kúrò, àwa a sì fò lọ.

10

11Ta ni ó mọ agbára ìbínú Rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù Rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Rẹ.

12Kọ́ wa bí a ti ń kàye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa bá a le fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

12

13Yípadà, OLÚWA! Yóò ti pẹ́ to? Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ.

14Tẹ́wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ, kí àwa kí o le kọrin fún ayọ̀ kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.

15Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ pípọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.

16Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ Rẹ̀ hàn àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ògo Rẹ̀ sì àwọn ọmọ wọn.

17Jẹ́ kí ẹwa OLÚWA Ọlọ́run wa wà lára wa; fí ìdí iṣẹ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa bẹ́ẹ̀ ní kí ó sì ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>