1Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ ọ̀gá ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
2Èmi yóò sọ nípa ti OLÚWA pé, “Òun ní ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.
2
3Ní tòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹkùn àwọn pẹyẹ pẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-àrùn búburú.
4Òun yóò fi ìyẹ́ Rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ Rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
5Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,
6Tàbí fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ń rìn kiri ni òkùnkùn, tàbí fún ìparun ti ń rin kirí ni ọ̀sán gangan.
7Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ, ẹgbàarùn ún ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ṣùgbọ́n kì yóò sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ
8Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú Rẹ àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.
8
9Nítorí ìwọ fi OLÚWA ṣe ààbò Rẹ, ìwọ fi Ọ̀ga Ògo ṣe ibùgbé Rẹ.
10Búburú kan ki yóò subu lù ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni àrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé Rẹ.
11ⓐ Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ ní gbogbo ọ̀nà Rẹ;
12Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ Rẹ̀ gún òkúta.
13ⓑ Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀; ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò nì ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀
13
14“Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ sì mi,” “èmi yóò gbà ọ́; èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dáa lóhùn; èmi yóò wà pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ipọ́nju, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”