1Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún OLÚWA àti láti máa kọrin sí orúkọ Rẹ̀, Ọ̀gá ògo,
2Láti kéde ìfẹ́ Rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ ní alẹ́
3Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá àti lára ohun èlò orin háàpù.
3
4Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ Rẹ OLÚWA; èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.
5Báwo ni isẹ́ Rẹ tí tóbi tó, OLÚWA, èrò inú Rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
6Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n, aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
7Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé.
7
8Ṣùgbọ́n ìwọ OLÚWA ni a ó gbéga títí láé.
9Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá Rẹ, OLÚWA, nítòótọ́ àwọn ọ̀ta Rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ní a ó fọ́nká.
10Ìwọ tí gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sími ní orí.
11Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀ta mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi.
11
12Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kédárì Lẹ́bánónì;
13Tí a gbìn si ilé OLÚWA, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni OLÚWA; òun ni àpáta mi, kò sì sí aburú kankan nínú Rẹ̀”