Ìwé Sáàmù 93:1-5 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA ń jọba, ọlá ńlá ní ó wọ̀ ní aṣọ; ọlá ńlá ni OLÚWA wọ̀ ní aṣọ àti ìhàmọ́ra Rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí.

2Ìjọba Rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayé raye.

2

3A ti gbé òkun sókè, OLÚWA, òkun ti gbé ohùn wọn sókè; òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.

4Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju òkun rírú lọ OLÚWA ga ní ògo.

4

5Ẹ̀rí Rẹ̀ dúró ṣinṣin; ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé Rẹ̀ lọ́sọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, OLÚWA.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>