Ìwé Sáàmù 94:1-23 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san, Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.

2Gbé ara Rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé; san ẹ̀san fún agbéraga ohun tí ó yẹ wọ́n.

3Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, OLÚWA tí àwọn ẹni búburú yóò kọ orin ayọ̀?

3

4Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbérága jáde; gbogbo àwọn olùṣebúburú kún fún ìṣògo.

5Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn Rẹ túútúú, OLÚWA: wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní Rẹ̀ lójú.

6Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,

7Wọ́n sọ pé, “OLÚWA kò rí i; Ọlọ́run Jákọ́bù kò sì kíyèsí i.”

7

8Kíyèsí i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

9Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bi? Ẹni tí ó dá ojú? Ó ha lè ṣe láìríran bi?

10Ẹni tí ń bá orílẹ̀ èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni sọ́nà bí? Ẹni ti ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

11ⓐ  OLÚWA mọ èrò inú ènìyàn; ó mọ̀ pé aṣán ni wọ́n.

11

12Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ báwí, OLÚWA, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin Rẹ;

13Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

14Nítorí OLÚWA kò ní kọ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀; Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní Rẹ̀ sílẹ̀.

15Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo, àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀ lé e lẹ́yìn.

15

16Ta ni yóò dìde fún mi sí àwọn olùṣe búburú? Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?

17Bí kò ṣe pé OLÚWA fún mi ní ìrànlọ́wọ́, èmi fẹ́rẹ̀ má a gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́

18Nígbà tí mo sọ pé “ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, OLÚWA, ìfẹ́ Rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.

19Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú Rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

19

20Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Rẹ ẹni tí ń fí òfin dìmọ̀ ìwà ìkà?

21Wọ́n kó ara wọn jọ si olódodo wọ́n sì ń dá àwọn aláìsẹ̀ lẹ́bi sí ikú.

22Ṣùgbọ́n, OLÚWA ti di odi alágbára mi, àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni tí mo ti ń gba ààbò.

23Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn OLÚWA Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>