1Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí OLÚWA Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2Ẹ jẹ́ kí a wá sí ìwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ kí a sì pòkìkí Rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò orin àti ìyìn.
2
3Nítorí OLÚWA Ọlọ́run títóbi ni, ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4Ní ọwọ́ Rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà, ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5Tirẹ̀ ni òkun, nítorí òun ni ó dá a àti ọwọ́ Rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
5
6Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a forí balẹ̀ kí a sìn-ín, Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú OLÚWA ẹni tí ó dá wa;
7ⓐ Nítorí òun ni Ọlọ́run wa àwa sì ni ènìyàn pápá Rẹ̀, àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ Rẹ̀
7Lónìí ti ìwọ bá gbọ́ ohùn Rẹ̀,
8Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Méríbà, àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ni Másà ni ihà,
9Nígbà ti àwọn baba yin dán mi wò ti wọn wádìí mi, ti wọn sì ri iṣẹ́ mi
10Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà; mo wí pé, “Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn sáko lọ wọn kò sì mọ ọ̀nà mi”.
11Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi “Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.”