Ìwé Sáàmù 96:1-13 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ẹ kọrin tuntun sí OLÚWA: Ẹ kọrin sí OLÚWA gbogbo ayé.

2Ẹ kọrin sí OLÚWA, yin orúkọ Rẹ̀ ẹ sọ ti ìgbàlà Rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́

3Ẹ sọ ti ògo Rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ láàrin gbogbo ènìyàn.

3

4Nítorí títóbi ní OLÚWA ẹni tí ìyìn tọ sí; òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìsà lọ

5Nítorí aṣán ni gbogbo àwọn òrìsà orílẹ̀ èdè ṣùgbọ́n OLÚWA dá àwọn ọ̀run

6Ọlá àti ọlá ńlá wà ni ìwájú Rẹ̀ agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ Rẹ̀.

6

7Ẹ fi fún OLÚWA, ẹ yin ìbátan ènìyàn Ẹ fi agbára àti ògo fún OLÚWA

8Ẹ fi ògo tí o tọ́ sí OLÚWA fún un; ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá Rẹ̀

9Ẹ máa sin OLÚWA ninú ẹwà ìwà mímọ́ Rẹ̀; ẹ wárìrì níwájú Rẹ̀ gbogbo ayé.

9

10Sọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, “OLÚWA jọba a fi ìdí ayé mú lẹ̀, tí kò sì lè yí; ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.”

11Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì dùn jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú Rẹ̀.

12Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀ àti ohun gbogbo ti ń bẹ nínú Rẹ̀: nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀

13Wọn yóò kọrin níwájú OLÚWA, nítorí ti ó ń bọ́ wá, òun bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fí òtítọ́ Rẹ̀ ṣe.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>